Monday, 12 September 2016

YORUBA RONU JINLE GIDIGIDI

YORUBA RONU JINLE GIDIGIDI

Eyin Eniyan mi ni ile ka a ro o o ji ire, Bawo ni e se nronu si ti iya nje omo Oduduwa, ti a ko si ri eni ni idi osan ti a wa nmu kikan. Gbogbo ekun yooku ko je iya ofin to Omo Oduduwa, ki i lo wa de ti omo eleran wa wa nje egungun. Kinni omo Yoruba nfe ti a ko ri ni ayika a wa. Ohun mere mere orisirisi ni Olorun Oba fi ji nki i wa sugbon a ko lati lo o. Awa to ye ki o je adari wa di eni amusin. O to akoko Omo oduduwa e dide e ji giri ki e sara giri. e je ki a pada si ese aaro o wa. Ki gbogbo ijoba Ipinle ronu piwada, ki won o yee din dundu iya fun omo iya a won mo. Enikan nii kuniku bo ba dale. Mo fe ki e ranti pe "Bi a ba ba eede je nitori Ede ti a nlo, e ma gbagbe pe Eede la o fabo si bi a ba ti Ede de.  

Oro mbo nko ti i de. Se oro ni mu mo ko moro wa. Agba ti o ba je aje e wehin ori ara re ni yoo fi ru eru dele. E ranti awon ti o ti se ijoba ri to renije, kinni igbeyin won. Igbeyin ni ki e maa ro ki e to se ohun kohun. Osise dabi ole. Mekunu wa di agbegba agbe. Mo mo daju wipe bi iwo ba ko, Olorun yoo gbe okuta dide. godsprudence.blogspot.com

No comments: